Saturday, 4 March 2017
Obinrin Yorùbá
Awa Obinrin Yorùbá, awa ni aya rere lode oko. Ade ori Okowa. iyawo Okunrin.
iya Okunrin. Olori lafin oko. Olori lafin Oba. Oluranlowo oko. Anse itoju oko.
Anfun oko wa lonje lasiko.
Obinrin Yorùbá, rewa lopolopo
-------------------
Bi Obinrin Yorùbá ba soro, a ma dun leti bi ti ohun eye Awoko.
Obinrin Yorùbá, oni wa tutu bi adaba. Obinrin Yorùbá, fi gbogbo ara sewa.
Obinrin Yorùbá, fi gbogbo ara sowo. Obinrin Yorùbá, fi gbogbo ara somo.
Oreke lewa. Ari ma le lo awoo pada seyin. Aguntasolo. Eleyin ju ege.
Eyin fun jowo. Adumaradan. Dudu bi korosin. Apon bepore. Ibadi aran.
Obinrin kukuru toun pe eni gigun ranse. Obinrin rogbodo bi olele awe.
Bebe idi awa Obinrin Yorùbá, a ma gbeleke duro, asi tun ma fin pon
awon omo wa ni apon ye.
Awa Obirin Yorùbá, iya rere laje fun awon omo wa.
Bi Obinrin n'ife Okunrin kan, a di alomoko.
Bi Obinrin ba loyun, won a ma ki pe eku Ikunra
Bi Obinrin bi omo, won a ki pe eku ewu omo
Bi Obinrin ba wa fi oju kan ela, araye won a bun laso.
Bi Okunrin o ni Obinrin n'ile a ma kanra..........................
GOD bless Otunba Dr. Gani Adams, the Convener of OPU Worldwide
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment